Business

Olumo Rock - One Of Nigeria's Natural Wonders

World News

A Yoruba Perspective


From The BBC

Mo bù sẹ́kún nígbà tí mo rí fọ́nrán àwọn èèyàn kan tó ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí mi ò lọ́kọ - Funke Akindele
O ni oun wo fọnran kan lori ayelujara nibi ti awọn eeyan kan ti n fi ṣe yẹyẹ nitori oun ko ni ade ori, ti eyi si gba omije loju rẹ.


Darandaran tó fi mààlúù jẹko l'Ondo gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá
Ire oko to to miliọnu lọna aadọta naira (50m) ni wọn lo bajẹ.


Mọ̀ nípa àtunṣe márùn-un ti INEC fẹ́ẹ́ ṣe sí òfin ìdìbò ilẹ̀ Naijiria
Ọkan lara awọn atunṣe pataki ti INEC n beere ni pe kawọn oṣiṣẹ eleto idibo, awọn agbofinro, oniroyin, dokita ati bẹẹ bẹẹ lọ, maa dibo tiwọn ko too di ọjọ idibo gan-an.


A ò gbà pé ìdájọ́ òdodo ti wáyé lórí ikú Bamise tí awakọ̀ BRT pa - Ẹbí Bamise Ayanwola fárígá lẹ́yìn ìdájọ́
Gẹgẹ bi igbimọ olupẹjọ ti ṣalaye, ni nnkan bi ago meje alẹ ni wọn fipa ba Bamise lopọ ti wọn si tun ṣeku pa a lopopona Lekki-Ajah ati afara Carter Bridge.


A ò bá ohun ìgbéṣùmọ̀mí lára Nnamdi Kanu -Ẹlẹ́rìí tí DSS pè
Olùjẹ́rìí kan tó pé ara à rẹ ní AAA sọ èyí nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè lọ́wọ́ agbẹjọ́rò Nnamdi Kanu, Kanu Agabi.


Ìná tún sọ ní Ibadan, ọ̀pọ̀ dúkìá tún báa lọ
Idaji Ọjọ Ẹti ni ijamba ina naa ṣẹlẹ


A ṣe àṣìṣe fífi ẹ̀sùn jìbìtì kan NELFUND- ICPC
Eto ẹyawo naa ni ijọba apapọ gbe kalẹ labẹ eto NELFUND.


A ò gbà pé ìdájọ́ òdodo ti wáyé lórí ikú Bamise tí awakọ̀ BRT pa - Ẹbí Bamise Ayanwola fárígá lẹ́yìn ìdájọ́
Gẹgẹ bi igbimọ olupẹjọ ti ṣalaye, ni nnkan bi ago meje alẹ ni wọn fipa ba Bamise lopọ ti wọn si tun ṣeku pa a lopopona Lekki-Ajah ati afara Carter Bridge.


NIMC ṣe àfikún iye owó ìforúkọsílẹ̀ àti àtúnṣe NIN
Lẹsẹkẹsẹ ni afikun tuntun yii yoo bẹrẹ.


Lẹ́yìn ọdún mẹta, erò ọkọ̀ ojú irin pàdé ẹni to jì i gbe ní mọ́ṣáláṣí
Ọkunrin kan, Kọmureedi M.B Muhammad, ẹni to jẹ ọkan lara awọn ero ọkọ oju irin reluwee tawọn ajinigbe ji gbe loṣu Kẹta ọdun 2022, lo pade ọkan lara awọn to ji wọn gbe nigba naa.


E-Money kìlọ̀ lẹ́yìn tó bọ́ lọ́wọ́ EFCC - Ẹ yé tàbùkù owó náírà mọ́!
E-Money ti ajọ EFCC ṣẹṣẹ fi silẹ lẹyin ti wọn fọwọ ofin mu un lori ẹsun pe o tabuku naira ati owo ilẹ okeere sọ pe nina naira loju agbo tabuku owo naa.


Kúdẹ́fù, ẹrú tó di ẹmẹ̀wà Aláàfin tí kò sì gbọ́dọ̀ fi ààfin Ọ̀yọ́ sílẹ̀
Lara awọn wọlewọde Alaafin ni Kudẹfu jẹ, oye pataki si ni laafin Ọyọ.


Ṣé lóòótọ́ ni CBEX ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà ní Naijiria?
BBC Yoruba kan si awọn eeyan kan ti wọn si n ṣe CBEX labẹ aṣọ, gbogbo wọn ni wọn si fi idi rẹ mulẹ wi pe looto ni idokoowo ori ayelujara naa ti pade de.


Ọ̀rọ̀ Soun Ogbomoso àtí Ìmáàmù Àgbà tún ṣẹ́yọ, Iléẹjọ́ so Ìmáàmù lọ́wọ́kọ́ lórí ìfinijoyè, Soun ní ìkọjá-àyè ni
Lọsẹ to kọja ni Sheikh Ayilara fi oye Asiwaju/Baba Isale Adini ilẹ Ogbomoso da Sẹnẹtọ Adeseun to ṣoju ẹkun aarin gbungbun Oyo laarin ọdun 2011 si 2015 nile aṣofin agba l'Abuja lọla.


Darapọ̀ mọ́ wa lórí WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ


Wo bí ayẹyẹ ìgbadé Owa Obokun tuntun, Adesuyi Haastrup, yóò ṣe wáyé n'Ilesa
Ọba Adesuyi to ti figba kan ri jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Osun ni yoo jẹ Owa kọkandinlaadọta (49th) ilẹ Ijesa.


Nńkan ò ṣe mi o, mo wà láàyè -King Sunny Ade
Loju opo Instagram rẹ ni KSA ṣalaye ọrọ si lọjọ keji iroyin to kọkọ jade nipa alaafia rẹ, ati pe wọn ko ri i.


Owu Waterfalls, ibùdó afẹ́ 'tó léwu ní lílọ̀ láì mú ẹ̀ṣọ́ aláàbò dáni'
Omi atapata da silẹ, Owu Waterfalls yii wa lara awọn omi atapata da walẹ to ga julọ lorilẹ Afirika to si rẹwa pupọ fun oju.


Wọn ti ko ọmọ Naijiria 203 tó há sí Libya padà wálé
Ajọ International Organization for Migration (IOM) pẹlu ajọṣepọ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, 'National Emergency Management Agency' (NEMA), ni wọn ko wọn wale pẹlu awọn alẹnulọrọ mi-in.


Wo bí o ṣe lè mọ iléeṣẹ́ tó fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lu CAC
Ninu atẹjade CAC ni wọn ti kilọ pe pe ẹni to ba kuna lati forukọ ileeṣẹ rẹ silẹ yoo fi ẹwọn jura.


Ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí ISWAP jẹ́wọ́ pé àwọn ló pa èèyàn 26 ní Borno, kí lèyí túmọ̀ sí fún àbò Nàìjíríà?
Loju opo ayelujara Telegram wọn ni ISWAP ti jẹwọ pe ikọlu to pa awọn eeyan naa ko ṣẹyin awọn.


Àwọn òṣìṣẹ́ bínú sí ìjọba Naijiria láyàájọ́ ọjọ́ òṣìṣẹ́
Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ, (NLC) lorilẹede yii; Kọmureedi Joe Ajaero ati Festus Osifo(TUC), koro oju si ijọba Naijiria, pẹlu alaye pe ko yẹ ki oṣiṣẹ tun di atọrọjẹ lẹyin iṣẹ ti wọn n ṣe.


Ṣé lóòótọ́ ni Portable yóò ṣe ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta gẹ́gẹ́bí iléẹjọ́ ṣe pàṣẹ́?
Ọdun 2023 ni Portable ti wa lẹnu ẹjọ naa to da lori lilu eeyan kan ati jiji ohun elo orin.


Kí ni òfin sọ nípa títàbùkù owó ilẹ̀ òkèèrè tó mú E-Money wọ gbaga EFCC?
Ẹ̀sùn pé ó ṣe owó ilẹ̀ òkèèrè lọ́nà àìtọ́ ni gbajúmọ̀ náà ń kojú, bí wọ́n ṣe fẹ̀sùn kàn-án pé ó ná owó dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà lọ́nà àìtọ́ èyí tí wọ́n ní ó lòdì sí òfin Foreign Exchange Act.


Àtúntò tó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn alákóòṣo àti òṣìṣẹ́ 200 ní iléeṣẹ̀ ìfọporọ̀bì Naijiria, NNPCL, ohun tí a mọ̀ rèé
NNPCL jawe gbele ẹ bakan naa fawọn ọga agba mii nile iṣẹ ifọporọbi ọhun, lara wọn ni Ọgbẹni Bala Wunti to jẹ adari ẹka to n ri si okowo labẹ NNPCL.


Àwọn Boko Haram tí fídíò ṣàfihàn pé wọ́n balẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Oyo, ohun tí a mọ̀ rèé
Oju ọna marosẹ Ibadan ni wọn ni awọn Boko Haram ọhun ti n sọkalẹ sipinlẹ Oyo, ki wọn too da wọn duro.


Iná sọ lọ̀jà fóònù ní Ilorin, dúkìá olówo iyebíye, ọ̀pọ̀lọpọ̀ fóònù jóná
Ọpọlọpọ foonu tuntun ti wọn n ta pẹlu awọn eyi ti wọn n tunṣe lọwọ lo ba iṣẹlẹ ina ojiji naa lọ, gẹgẹ bi awọn tọrọ naa kan ṣe ṣalaye.


Kí nídìí tí ìjọba àpapọ̀ fi fẹ́ wọ́gilé ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ sílẹ̀ òkèèrè fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ lábẹ́ ètò BEA?
Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà, Tunji Alausa ló kéde ìpinnu ìjọba náà lásìkò tó gbàlejò ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.


Ó ti pé ọgọ́rùn-ún ọjọ́ tí Amẹrika dá owó ìrànwọ́ USAID sílẹ̀ òkèèrè dúró - àwọn wo ló pàdánù jùlọ?
Owo to to $63bn ni Amẹrika na lọdun 2024 gẹgẹ bii owo iranwọ silẹ okeere.


NDIC bẹ̀rẹ̀ sísan owó fún àwọn tó fowópamọ́ sí Heritage Bank to kógbáwọlé
Ni oṣu kẹfa ọdun 2024 ni Banki Heritage ti kogba wọle ti ọpọ awọn to fi owo pamọ sibẹ si ti n poungbe fun sisan owo wọn pada.


Lẹ́yìn ìsìnkú Póòpù Francis, Ìjọ Kátólíìkì kéde ọjọ́ tí wọn yóò yàn póòpù tuntun
Ọsan ọjọ akọkọ tiwọn ba wọ inu ipade idakọnkọ naa ni wọn yoo di ipele akọkọ idibo naa. Amọ, yoo to igba mẹrin ọtọọtọ ti wọn yoo maa dibo lojoojumọ lẹyin eyi.


Ṣé lóòótọ́ ni pé Naijiria ti di orílẹ̀èdè ẹlẹ́gbẹ́ òṣèlú kan?
Oloṣelu ki i deede fi ẹgbẹ to gbe wọn depo silẹ bẹẹ ki wọn lọọ maa darapọ mọ ẹgbẹ alatako, ṣugbọn ohun to n ṣẹlẹ lọwọ ni Naijiria ree.


Ṣé lóòtọ́ ni Gómìnà Adeleke ń gbèrò láti bẹ́ kìjà kúrò ní PDP lọ sí APC?
Ẹgbẹ Oṣelu APC ni Gomina Adeleke pẹlu ti kuro wa si ẹgbẹ oṣelu PDP lẹyin iku ẹgbọn rẹ, Isiaka Adeleke to jẹSẹnetọ lẹgbẹ oṣelu naa nigba naa lọhun.


Òṣìṣẹ́ Access Bank tó ya fídíò ìhòhò obìnrin 400 níbi iṣẹ yóò fojú ba ilé-ẹjọ́
Opin ọsẹ ni iroyin jade, pe oṣiṣẹ banki naa ya fidio ihoho awọn oṣiṣẹ obinrin ni banki ọhun, ti iye wọn to irinwo.


Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ Mínísítà lẹ́yìn ẹ̀sùn ìfipá bá ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún lò pọ̀
Hengari, ẹni ọdun mọkandinlọgọta (59), loun ko jẹbi ẹsun naa nigba to foju han ni kootu lọjọ Aje.


Àjọ NAPTIP dóòlà ọmọ Naijiria mẹ́sàn-an tí wọ́n fẹ́ẹ́ tàn ṣòwò ẹrú lọ si Libya
Aliyu Abubakar, adari ajọ naa fun ipinlẹ Zamfara, ṣalaye pe ẹnu ibode Babura, nipinlẹ Jigawa ni awọn ti doola awọn eeyan mẹsan-an naa.


Mi ò kábàmọ́ọ̀ pé ìyàwó mi tó kú nigbà tó fẹ́ bímọ kò forúkọ sílẹ̀ nílé ìwòsàn - Folajimi
Ọgbẹni Akinbobola Folajimi sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC pe kii ṣe ile iwosan loun bi awọn ọmọ oun meji toun ti bi ṣaaju si.


Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn tó ń fi èèyàn ṣòwò ẹrú ní Ibadan, dóòlà èèyàn 84
A gbọ pe pupọ ninu awọn ẹni ti ọlọpaa doola naa lo jẹ ọmọ orilẹede Democratic Republic of Congo ti wọn tan wa si Naijiria pẹlu ẹtan pe wọn yoo fun wọn ni iṣẹ.


Learning Never Stops

The Line Between Disorder And Order Lies In Logistics